Native Bible

Ezekiel 41:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìta ibi mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jùlọ ni ìlẹ̀kùn méjì papọ̀.

Ezekiel 41:23 in English

Ezekiel 41:23 · Berean Standard Bible

Both the outer sanctuary and the inner sanctuary had double doors,

Context

21Ìta ibi mímọ́ ni férémù onígun mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀kan tí ó wà ní Ibi Mímọ́ Jùlọ rí bákan náà. 22Pẹpẹ ìrúbọ kan tí a fi igi ṣe wà, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, àwọn igun rẹ̀, ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti ògiri rẹ́ jẹ́ igi. Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Èyí yìí ní tẹmpili tí ó wà ní iwájú Olúwa.” 23Ìta ibi mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jùlọ ni ìlẹ̀kùn méjì papọ̀. 24Lẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní ewé méjì méjì, ewé méjì tí a gbe kọ́ fún ẹnu-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan. 25Ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ìta ibi mímọ́ ni àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ tí a fín bí ti àwọn tí a fín si àwọn ara ògiri, ìbòrí tí á fi igi ṣe wà ní iwájú ẹnu-ọ̀nà ilé ní ìta.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.