Native Bible

Ezekiel 41:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní ewé méjì méjì, ewé méjì tí a gbe kọ́ fún ẹnu-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.

Ezekiel 41:24 in English

Ezekiel 41:24 · Berean Standard Bible

and each door had two swinging panels. There were two panels for one door and two for the other.

Context

22Pẹpẹ ìrúbọ kan tí a fi igi ṣe wà, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, àwọn igun rẹ̀, ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti ògiri rẹ́ jẹ́ igi. Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Èyí yìí ní tẹmpili tí ó wà ní iwájú Olúwa.” 23Ìta ibi mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jùlọ ni ìlẹ̀kùn méjì papọ̀. 24Lẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní ewé méjì méjì, ewé méjì tí a gbe kọ́ fún ẹnu-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan. 25Ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ìta ibi mímọ́ ni àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ tí a fín bí ti àwọn tí a fín si àwọn ara ògiri, ìbòrí tí á fi igi ṣe wà ní iwájú ẹnu-ọ̀nà ilé ní ìta. 26Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ògiri ẹnu-ọ̀nà ní àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú igi ọ̀pẹ tí a fín ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì wà. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà ni ìbòrí tí a fi igi ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.