Native Bible

Ezekiel 4:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.”

Ezekiel 4:13 in English

Ezekiel 4:13 · Berean Standard Bible

Then the LORD said, “This is how the Israelites will eat their defiled bread among the nations to which I will banish them.”

Context

11Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀. 12Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà barle; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.” 13Olúwa sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.” 14Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! Kò rí bẹ́ẹ̀ Olúwa Olódùmarè! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsin yìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí. Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí.” 15Nígbà náà ló wí fún mi pé, “Wò ó, Èmi ó fún ọ ní ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn. Èmi yóò mú ki ó dín àkàrà rẹ lórí ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.