Esekiẹli 4:11
Ezekiel 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀.
Ezekiel 4:11 in English
Ezekiel 4:11 · Berean Standard Bible
You are also to measure out a sixth of a hin of water * to drink, and you are to drink it at set times.
Context
9“Mú alikama, ọkà bàbà àti barle, erèé àti lẹntili, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390). 10Wọn òsùwọ̀n ogún ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀. 11Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀. 12Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà barle; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.” 13Olúwa sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.