Esekiẹli 36:18
Ezekiel 36:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́.
Ezekiel 36:18 in English
Ezekiel 36:18 · Berean Standard Bible
So I poured out My wrath upon them because of the blood they had shed on the land, and because they had defiled it with their idols.
Context
16Síwájú sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 17“Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi. 18Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́. 19Mo tú wọn ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn. 20Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.