Esekiẹli 36:17
Ezekiel 36:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi.
Ezekiel 36:17 in English
Ezekiel 36:17 · Berean Standard Bible
“Son of man, when the people of Israel lived in their land, they defiled it by their own ways and deeds. Their behavior before Me was like the uncleanness of a woman’s impurity.
Context
15Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀-èdè rẹ ṣubú, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ” 16Síwájú sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 17“Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi. 18Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́. 19Mo tú wọn ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.