Native Bible

Ezekiel 36:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’

Ezekiel 36:20 in English

Ezekiel 36:20 · Berean Standard Bible

And wherever they went among the nations, they profaned My holy name, because it was said of them, ‘These are the people of the LORD, yet they had to leave His land.’

Context

18Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́. 19Mo tú wọn ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn. 20Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’ 21Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Israẹli sọ di aláìmọ́ ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ. 22“Nítorí náà, sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Israẹli, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.