Native Bible

Ezekiel 34:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn.

Ezekiel 34:6 in English

Ezekiel 34:6 · Berean Standard Bible

My flock went astray on all the mountains and every high hill. They were scattered over the face of all the earth, with no one to search for them or seek them out.’

Context

4Ìwọ kò ì tí ì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa. Ìwọ kò í tí ì mú aṣáko padà tàbí wá ẹni tí ó nù. Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò. 5Nítorí náà wọn fọ́n káàkiri nítorí àìsí olùṣọ́-àgùntàn, nígbà tí wọ́n fọ́nká tán wọn di ìjẹ fún gbogbo ẹranko búburú. 6Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn. 7“ ‘Nítorí náà, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 8Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè ní Olúwa Olódùmarè wí, nítorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́-àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn mi kò ṣe àwárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.