Esekiẹli 34:5
Ezekiel 34:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà wọn fọ́n káàkiri nítorí àìsí olùṣọ́-àgùntàn, nígbà tí wọ́n fọ́nká tán wọn di ìjẹ fún gbogbo ẹranko búburú.
Ezekiel 34:5 in English
Ezekiel 34:5 · Berean Standard Bible
They were scattered for lack of a shepherd, and when they were scattered they became food for all the wild beasts.
Context
3Ìwọ jẹ wàrà. O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran. 4Ìwọ kò ì tí ì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa. Ìwọ kò í tí ì mú aṣáko padà tàbí wá ẹni tí ó nù. Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò. 5Nítorí náà wọn fọ́n káàkiri nítorí àìsí olùṣọ́-àgùntàn, nígbà tí wọ́n fọ́nká tán wọn di ìjẹ fún gbogbo ẹranko búburú. 6Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn. 7“ ‘Nítorí náà, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.