Esekiẹli 34:8
Ezekiel 34:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè ní Olúwa Olódùmarè wí, nítorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́-àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn mi kò ṣe àwárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi,
Ezekiel 34:8 in English
Ezekiel 34:8 · Berean Standard Bible
‘As surely as I live, declares the Lord GOD, because My flock lacks a shepherd and has become prey and food for every wild beast, and because My shepherds did not search for My flock but fed themselves instead,
Context
6Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn. 7“ ‘Nítorí náà, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 8Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè ní Olúwa Olódùmarè wí, nítorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́-àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn mi kò ṣe àwárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi, 9nítorí náà, ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 10Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìlòdì sí àwọn Olùṣọ́-àgùntàn, èmi yóò sì béèrè agbo ẹran mi lọ́wọ́ wọn. Èmi yóò sì mú wọn dẹ́kun àti máa darí agbo ẹran mi, tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà kò sì ní lè bọ́ ara wọn mọ́. Èmi yóò gba agbo ẹran mi kúrò ni ẹnu wọn, kì yóò sì jẹ́ oúnjẹ fún wọn mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.