Native Bible

Ezekiel 34:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò fi Olùṣọ́-àgùntàn kan ṣe olórí wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi, òun yóò sì tọ́jú wọn; òun yóò bọ́ wọn yóò sì jẹ́ Olùṣọ́-àgùntàn wọn.

Ezekiel 34:23 in English

Ezekiel 34:23 · Berean Standard Bible

I will appoint over them one shepherd, My servant David, and he will feed them. He will feed them and be their shepherd.

Context

21Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ, 22Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́. Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn kan àti òmíràn. 23Èmi yóò fi Olùṣọ́-àgùntàn kan ṣe olórí wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi, òun yóò sì tọ́jú wọn; òun yóò bọ́ wọn yóò sì jẹ́ Olùṣọ́-àgùntàn wọn. 24Èmi Olúwa yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi yóò jẹ́ ọmọ-aládé láàrín wọn. Èmi Olúwa ní o sọ̀rọ̀. 25“ ‘Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, èmi yóò sì gba ilẹ̀ náà kúrò lọ́wọ́ ẹranko búburú, kí wọn kí o lè gbé ní aṣálẹ̀, kí àgùntàn sì gbé ní inú igbó ní àìléwu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.