Esekiẹli 34:24
Ezekiel 34:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi Olúwa yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi yóò jẹ́ ọmọ-aládé láàrín wọn. Èmi Olúwa ní o sọ̀rọ̀.
Ezekiel 34:24 in English
Ezekiel 34:24 · Berean Standard Bible
I, the LORD, will be their God, and My servant David will be a prince among them. I, the LORD, have spoken.
Context
22Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́. Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn kan àti òmíràn. 23Èmi yóò fi Olùṣọ́-àgùntàn kan ṣe olórí wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi, òun yóò sì tọ́jú wọn; òun yóò bọ́ wọn yóò sì jẹ́ Olùṣọ́-àgùntàn wọn. 24Èmi Olúwa yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi yóò jẹ́ ọmọ-aládé láàrín wọn. Èmi Olúwa ní o sọ̀rọ̀. 25“ ‘Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, èmi yóò sì gba ilẹ̀ náà kúrò lọ́wọ́ ẹranko búburú, kí wọn kí o lè gbé ní aṣálẹ̀, kí àgùntàn sì gbé ní inú igbó ní àìléwu. 26Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká. Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò; òjò ìbùkún yóò sì wà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.