Esekiẹli 34:21
Ezekiel 34:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ,
Ezekiel 34:21 in English
Ezekiel 34:21 · Berean Standard Bible
Since you shove with flank and shoulder, butting all the weak ones with your horns until you have scattered them abroad,
Context
19Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀? 20“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún wọn: Wò ó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù. 21Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ, 22Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́. Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn kan àti òmíràn. 23Èmi yóò fi Olùṣọ́-àgùntàn kan ṣe olórí wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi, òun yóò sì tọ́jú wọn; òun yóò bọ́ wọn yóò sì jẹ́ Olùṣọ́-àgùntàn wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.