Native Bible

Ezekiel 32:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Ezekiel 32:16 in English

Ezekiel 32:16 · Berean Standard Bible

This is the lament they will chant for her; the daughters of the nations will chant it. Over Egypt and all her multitudes they will chant it, declares the Lord GOD.”

Context

14Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo, ni Olúwa Olódùmarè wí. 15Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro, tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò. Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ 16“Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.” 17Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá: 18“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún lórí Ejibiti kí o sì ránṣẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.