Esekiẹli 32:14
Ezekiel 32:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo, ni Olúwa Olódùmarè wí.
Ezekiel 32:14 in English
Ezekiel 32:14 · Berean Standard Bible
Then I will let her waters settle and will make her rivers flow like oil,’ declares the Lord GOD.
Context
12Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó
tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú
àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ.
Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká,
gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀. 13Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun
ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi
kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀
ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni ẹrọ̀fọ̀. 14Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò
kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo,
ni Olúwa Olódùmarè wí. 15Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro,
tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò.
Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀,
nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ 16“Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.