Esekiẹli 30:20
Ezekiel 30:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ keje oṣù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá,
Ezekiel 30:20 in English
Ezekiel 30:20 · Berean Standard Bible
In the eleventh year, on the seventh day of the first month, the word of the LORD came to me, saying,
Context
18Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi
nígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò;
níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin
wọn yóò fi ìkùùkuu bò ó
àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn. 19Nítorí náà, Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Ejibiti,
wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ” 20Ní ọjọ́ keje oṣù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá, 21“Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣẹ́ apá Farao ọba Ejibiti. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a kò sì ti di i si àárín igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú. 22Nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí Farao ọba Ejibiti. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.