Esekiẹli 28:15
Ezekiel 28:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí a ti dá ọ, títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
Ezekiel 28:15 in English
Ezekiel 28:15 · Berean Standard Bible
From the day you were created you were blameless in your ways— until wickedness was found in you.
Context
13Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run;
onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ;
sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì,
àti jasperi, safire, emeradi,
turikuose, àti karbunkili, àti wúrà,
ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà,
láti ara wúrà,
ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn. 14A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,
torí èyí ni mo fi yàn ọ́.
Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;
ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná. 15Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ,
láti ọjọ́ tí a ti dá ọ,
títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ. 16Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ,
ìwọ kún fún ìwà ipá;
ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀.
Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù,
bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.
Èmi sì pa ọ run,
ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná. 17Ọkàn rẹ gbéraga,
nítorí ẹwà rẹ.
Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,
nítorí dídára rẹ.
Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;
mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.