Native Bible

Ezekiel 28:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

Ezekiel 28:11 in English

Ezekiel 28:11 · Berean Standard Bible

Again the word of the LORD came to me, saying,

Context

9Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” ní ojú àwọn tí ó pa ọ́? Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́. 10Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà, ní ọwọ́ àwọn àjèjì. Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ” 11Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 12“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà, o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà. 13Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run; onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ; sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì, àti jasperi, safire, emeradi, turikuose, àti karbunkili, àti wúrà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà, láti ara wúrà, ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.