Esekiẹli 27:33
Ezekiel 27:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.
Ezekiel 27:33 in English
Ezekiel 27:33 · Berean Standard Bible
When your wares went out to sea, you satisfied many nations. You enriched the kings of the earth with your abundant wealth and merchandise.
Context
31Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ
wọn yóò wọ aṣọ yíya
wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú
ìkorò ọkàn nítorí rẹ
pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò. 32Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ
wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé:
“Ta ni ó dàbí Tire
èyí tí ó parun ní àárín Òkun?” 33Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá
ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn
ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ
sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀. 34Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú
nínú ibú omi;
nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ
ní àárín rẹ,
ni yóò ṣubú. 35Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé
ní erékùṣù náà sí ọ
jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn,
ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.