Esekiẹli 24:4
Ezekiel 24:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀, gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá. Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀,
Ezekiel 24:4 in English
Ezekiel 24:4 · Berean Standard Bible
Put in the pieces of meat, every good piece— thigh and shoulder— fill it with choice bones.
Context
2“Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí ọba Babeli náà ti da ojú ti Jerusalẹmu ní ọjọ́ yìí gan an. 3Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná,
gbé e ka iná kí o sì da omi sí i nínú. 4Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀,
gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá.
Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀, 5mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran.
Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀;
sì jẹ́ kí ó hó dáradára
sì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀. 6Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà,
fún ìkòkò náà tí èérí rẹ̀ wà nínú rẹ̀,
tí èérí kò dà kúrò lójú rẹ̀!
Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí
má ṣe ṣà wọ́n mú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.