Esekiẹli 19:8
Ezekiel 19:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i, àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá. Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn.
Ezekiel 19:8 in English
Ezekiel 19:8 · Berean Standard Bible
Then the nations set out against him from the provinces on every side. They spread their net over him; he was trapped in their pit.
Context
6Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára,
o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn. 7Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro.
Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀. 8Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i,
àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá.
Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un,
wọn sì mú nínú ihò wọn. 9Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli,
wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli. 10“ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀;
tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso,
ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.