Esekiẹli 19:6
Ezekiel 19:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára, o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.
Ezekiel 19:6 in English
Ezekiel 19:6 · Berean Standard Bible
He prowled among the lions, and became a young lion. After learning to tear his prey, he devoured men.
Context
4Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀,
wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn.
Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti. 5“ ‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán,
ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára. 6Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára,
o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn. 7Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro.
Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀. 8Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i,
àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá.
Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un,
wọn sì mú nínú ihò wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.