Esekiẹli 18:22
Ezekiel 18:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kà á sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè.
Ezekiel 18:22 in English
Ezekiel 18:22 · Berean Standard Bible
None of the transgressions he has committed will be held against him. Because of the righteousness he has practiced, he will live.
Context
20Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburú náà la ó kà sí i lọ́rùn. 21“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àṣẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú. 22A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kà á sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè. 23Ǹjẹ́ èmi ha ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní Olúwa Olódùmarè wí pé, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ kí ó sì yè? 24“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì tún ń ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kì yóò rántí ọ̀kankan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.