Esekiẹli 18:24
Ezekiel 18:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì tún ń ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kì yóò rántí ọ̀kankan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.
Ezekiel 18:24 in English
Ezekiel 18:24 · Berean Standard Bible
But if a righteous man turns from his righteousness and practices iniquity, committing the same abominations as the wicked, will he live? None of the righteous acts he did will be remembered. Because of the unfaithfulness and sin he has committed, he will die.
Context
22A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kà á sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè. 23Ǹjẹ́ èmi ha ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní Olúwa Olódùmarè wí pé, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ kí ó sì yè? 24“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì tún ń ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kì yóò rántí ọ̀kankan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú. 25“Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin tún wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò gún.’ Gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ ilé Israẹli. Ọ̀nà mi ni kò ha gún? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà tiyín gan an ni kò gún? 26Bí olódodo ba yípadà kúrò nínú olódodo rẹ̀, tó sì dẹ́ṣẹ̀, yóò ku fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.