Esekiẹli 17:3
Ezekiel 17:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi kedari tó ga jùlọ,
Ezekiel 17:3 in English
Ezekiel 17:3 · Berean Standard Bible
and tell them that this is what the Lord GOD says: ‘A great eagle with great wings and long pinions,* full of feathers of many colors, came to Lebanon and took away the top of the cedar.
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ní wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Israẹli. 3Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi kedari tó ga jùlọ, 4ó gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, ó mú un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn oníṣòwò. 5“ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.