Native Bible

Exodus 8:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò pààlà sáàárín àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ”

Exodus 8:23 in English

Exodus 8:23 · Berean Standard Bible

I will make a distinction * between My people and your people. This sign will take place tomorrow.’”

Context

21Bí ìwọ kò bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, èmi yóò rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sí ara rẹ àti sí ara àwọn ìjòyè rẹ, àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ̀, sí àwọn ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ilé àwọn ará Ejibiti ni yóò kún fún eṣinṣin àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú. 22“ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, Èmi yóò ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí. 23Èmi yóò pààlà sáàárín àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ” 24Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Farao àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Ejibiti bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì. 25Nígbà náà ni Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.