Native Bible

Exodus 8:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ìwọ kò bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, èmi yóò rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sí ara rẹ àti sí ara àwọn ìjòyè rẹ, àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ̀, sí àwọn ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ilé àwọn ará Ejibiti ni yóò kún fún eṣinṣin àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú.

Exodus 8:21 in English

Exodus 8:21 · Berean Standard Bible

But if you will not let My people go, I will send swarms of flies * upon you and your officials and your people and your houses. The houses of the Egyptians and even the ground where they stand will be full of flies.

Context

19àwọn onídán sì sọ fún Farao pé, “Ìka Ọlọ́run ni èyí.” Ṣùgbọ́n àyà Farao sì yigbì, kò sì fetísílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ. 20Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí o sì ko Farao lójú bí ó ṣe ń lọ sí odò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó bá à lè sìn Mi. 21Bí ìwọ kò bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, èmi yóò rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sí ara rẹ àti sí ara àwọn ìjòyè rẹ, àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ̀, sí àwọn ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ilé àwọn ará Ejibiti ni yóò kún fún eṣinṣin àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú. 22“ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, Èmi yóò ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí. 23Èmi yóò pààlà sáàárín àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.