Native Bible

Exodus 8:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Farao àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Ejibiti bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì.

Exodus 8:24 in English

Exodus 8:24 · Berean Standard Bible

And the LORD did so. Thick swarms of flies poured into Pharaoh’s palace and into the houses of his officials. Throughout Egypt the land was ruined by swarms of flies.

Context

22“ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, Èmi yóò ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí. 23Èmi yóò pààlà sáàárín àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ” 24Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Farao àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Ejibiti bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì. 25Nígbà náà ni Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.” 26Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Ejibiti. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn, ó ní sọ òkúta lù wá?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.