Eksodu 7:17
Exodus 7:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni Olúwa wí, nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Naili yóò sì di ẹ̀jẹ̀.
Exodus 7:17 in English
Exodus 7:17 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says: By this you will know that I am the LORD. Behold, with the staff in my hand I will strike the water of the Nile, and it will turn to blood.
Context
15Tọ Farao lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Naili láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ. 16Sọ fún un pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni aginjù. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba. 17Èyí ni Olúwa wí, nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Naili yóò sì di ẹ̀jẹ̀. 18Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Naili yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Ejibiti kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ” 19Olúwa sọ fún Mose, “Sọ fún Aaroni, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Ejibiti. Lórí àwọn odò kéékèèké àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi, wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀.’ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Ejibiti, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.