Eksodu 7:15
Exodus 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tọ Farao lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Naili láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ.
Exodus 7:15 in English
Exodus 7:15 · Berean Standard Bible
Go to Pharaoh in the morning as you see him walking out to the water. Wait on the bank of the Nile to meet him, and take in your hand the staff that was changed into a snake.
Context
13Síbẹ̀ ọkàn Farao sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ. 14Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti di líle, ó kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ó lọ. 15Tọ Farao lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Naili láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ. 16Sọ fún un pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni aginjù. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba. 17Èyí ni Olúwa wí, nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Naili yóò sì di ẹ̀jẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.