Eksodu 7:18
Exodus 7:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Naili yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Ejibiti kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ”
Exodus 7:18 in English
Exodus 7:18 · Berean Standard Bible
The fish in the Nile will die, the river will stink, and the Egyptians will be unable to drink its water.’”
Context
16Sọ fún un pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni aginjù. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba. 17Èyí ni Olúwa wí, nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Naili yóò sì di ẹ̀jẹ̀. 18Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Naili yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Ejibiti kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ” 19Olúwa sọ fún Mose, “Sọ fún Aaroni, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Ejibiti. Lórí àwọn odò kéékèèké àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi, wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀.’ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Ejibiti, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.” 20Mose àti Aaroni sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Naili, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.