Eksodu 6:15
Exodus 6:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ Simeoni ni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu ọmọ obìnrin Kenaani. Àwọn wọ̀nyí ni ìran Simeoni.
Exodus 6:15 in English
Exodus 6:15 · Berean Standard Bible
The sons of Simeon were Jemuel, Jamin, Ohad, Jachin, Zohar,* and Shaul, the son of a Canaanite woman. These were the clans of Simeon.
Context
13Olúwa bá ìran Mose àti Aaroni sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Israẹli àti Farao ọba Ejibiti, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. 14Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn:
àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni:
Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi.
Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Reubeni. 15Àwọn ọmọ Simeoni ni:
Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu ọmọ obìnrin Kenaani.
Àwọn wọ̀nyí ni ìran Simeoni. 16Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:
Gerṣoni, Kohati àti Merari.
Lefi lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé. 17Àwọn ọmọ Gerṣoni ni ìran wọn ni:
Libni àti Ṣimei.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.