Eksodu 5:18
Exodus 5:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.”
Exodus 5:18 in English
Exodus 5:18 · Berean Standard Bible
Now get to work. You will be given no straw, yet you must deliver the full quota of bricks.”
Context
16Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.” 17Farao sí dáhùn wí pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ọ̀lẹ! Èyí ni ó mú kí ẹ̀yin máa sọ ní ìgbà gbogbo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Olúwa.’ 18Nísinsin yìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.” 19Àwọn ọmọ Israẹli tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.” 20Ní ìgbà tí wọ́n kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao wọ́n rí Mose àti Aaroni tí ó dúró láti pàdé wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.