Native Bible

Exodus 5:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”

Exodus 5:16 in English

Exodus 5:16 · Berean Standard Bible

No straw has been given to your servants, yet we are told, ‘Make bricks!’ Look, your servants are being beaten, but the fault is with your own people.”

Context

14Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao yàn lára ọmọ Israẹli ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?” 15Nígbà náà ni àwọn alábojútó iṣẹ́ tí a yàn lára àwọn ọmọ Israẹli tọ Farao lọ láti lọ bẹ̀bẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ọwọ́ líle mú àwa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ báyìí? 16Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.” 17Farao sí dáhùn wí pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ọ̀lẹ! Èyí ni ó mú kí ẹ̀yin máa sọ ní ìgbà gbogbo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Olúwa.’ 18Nísinsin yìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.