Native Bible

Exodus 5:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ Israẹli tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.”

Exodus 5:19 in English

Exodus 5:19 · Berean Standard Bible

The Israelite foremen realized they were in trouble when they were told, “You must not reduce your daily quota of bricks.”

Context

17Farao sí dáhùn wí pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ọ̀lẹ! Èyí ni ó mú kí ẹ̀yin máa sọ ní ìgbà gbogbo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Olúwa.’ 18Nísinsin yìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.” 19Àwọn ọmọ Israẹli tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.” 20Ní ìgbà tí wọ́n kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao wọ́n rí Mose àti Aaroni tí ó dúró láti pàdé wọn. 21Wọn sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó wò yín, kí ó sì ṣe ìdájọ́! Ẹ̀yin ti mú wa dàbí òórùn búburú fún Farao àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, ẹ sì ti fún wọn ni idà láti fi pa wá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.