Native Bible

Exodus 4:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà Olúwa yọ̀ǹda rẹ láti ìgbà tí ó ti wí pé, “Ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ í ṣe.” Èyí tó túmọ̀ sí ìkọlà abẹ́.

Exodus 4:26 in English

Exodus 4:26 · Berean Standard Bible

So the LORD let him alone. (When she said, “bridegroom of blood,” she was referring to the circumcision.)

Context

24Ní ọ̀nà ìrìnàjò rẹ, ni ibi tí wọ́n gbé sùn ní ilé èrò ní alẹ́, Olúwa pàdé Mose, ó sì fẹ́ láti pa á. 25Ṣùgbọ́n Sippora mú ọ̀bẹ òkúta mímú, ó sì kọ ọmọ rẹ̀ ní ilà abẹ́, ó sì fi awọ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ Mose. Sippora sì wí pé, “Ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ jẹ́ sí mi.” 26Nítorí náà Olúwa yọ̀ǹda rẹ láti ìgbà tí ó ti wí pé, “Ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ í ṣe.” Èyí tó túmọ̀ sí ìkọlà abẹ́. 27Olúwa sì sọ fún Aaroni pé, “Lọ sínú aginjù láti lọ pàdé Mose.” Ní ìgbà náà ni ó lọ pàdé Mose ní orí òkè Ọlọ́run, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 28Ní ìgbà náà ni Mose sì sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti rán fún Aaroni àti nípa gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa ti pàṣẹ fún un láti ṣe ní iwájú Farao.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.