Native Bible

Exodus 4:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Sippora mú ọ̀bẹ òkúta mímú, ó sì kọ ọmọ rẹ̀ ní ilà abẹ́, ó sì fi awọ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ Mose. Sippora sì wí pé, “Ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ jẹ́ sí mi.”

Exodus 4:25 in English

Exodus 4:25 · Berean Standard Bible

But Zipporah took a flint knife, cut off her son’s foreskin, and touched it to Moses’ feet.* “Surely you are a bridegroom of blood to me,” she said.

Context

23mo sọ fún ọ, “Jẹ́ kí ọmọ mi lọ, ki òun kí ó lè máa sìn mí.” Ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti jẹ́ kí ó lọ; nítorí náà, èmi yóò pa àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin.’ ” 24Ní ọ̀nà ìrìnàjò rẹ, ni ibi tí wọ́n gbé sùn ní ilé èrò ní alẹ́, Olúwa pàdé Mose, ó sì fẹ́ láti pa á. 25Ṣùgbọ́n Sippora mú ọ̀bẹ òkúta mímú, ó sì kọ ọmọ rẹ̀ ní ilà abẹ́, ó sì fi awọ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ Mose. Sippora sì wí pé, “Ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ jẹ́ sí mi.” 26Nítorí náà Olúwa yọ̀ǹda rẹ láti ìgbà tí ó ti wí pé, “Ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ í ṣe.” Èyí tó túmọ̀ sí ìkọlà abẹ́. 27Olúwa sì sọ fún Aaroni pé, “Lọ sínú aginjù láti lọ pàdé Mose.” Ní ìgbà náà ni ó lọ pàdé Mose ní orí òkè Ọlọ́run, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.