Eksodu 4:19
Exodus 4:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí, Olúwa ti sọ fún Mose ni ilẹ̀ Midiani pé, “Máa padà lọ sí Ejibiti, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.”
Exodus 4:19 in English
Exodus 4:19 · Berean Standard Bible
Now the LORD had said to Moses in Midian, “Go back to Egypt, for all the men who sought to kill you are dead.”
Context
17Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.” 18Mose padà sí ọ̀dọ̀ Jetro baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Ejibiti láti wò bóyá wọ́n ṣì wà láààyè síbẹ̀.”
Jetro sì dáhùn, ó wí pé, “Máa lọ ni àlàáfíà.” 19Nísinsin yìí, Olúwa ti sọ fún Mose ni ilẹ̀ Midiani pé, “Máa padà lọ sí Ejibiti, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.” 20Mose mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Ejibiti. Ó sì mú ọ̀pá Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀. 21Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Ejibiti rí i pé ìwọ ṣe iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Farao. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì sé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.