Eksodu 4:18
Exodus 4:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose padà sí ọ̀dọ̀ Jetro baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Ejibiti láti wò bóyá wọ́n ṣì wà láààyè síbẹ̀.” Jetro sì dáhùn, ó wí pé, “Máa lọ ni àlàáfíà.”
Exodus 4:18 in English
Exodus 4:18 · Berean Standard Bible
Then Moses went back to his father-in-law Jethro * and said to him, “Please let me return to my brothers in Egypt to see if they are still alive.” “Go in peace,” Jethro replied.
Context
16Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀. 17Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.” 18Mose padà sí ọ̀dọ̀ Jetro baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Ejibiti láti wò bóyá wọ́n ṣì wà láààyè síbẹ̀.”
Jetro sì dáhùn, ó wí pé, “Máa lọ ni àlàáfíà.” 19Nísinsin yìí, Olúwa ti sọ fún Mose ni ilẹ̀ Midiani pé, “Máa padà lọ sí Ejibiti, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.” 20Mose mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Ejibiti. Ó sì mú ọ̀pá Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.