Native Bible

Exodus 38:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀.

Exodus 38:12 in English

Exodus 38:12 · Berean Standard Bible

The west side was fifty cubits long * and had curtains, with ten posts and ten bases. The hooks and bands of the posts were silver.

Context

10pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 11Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 12Ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀. 13Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀. 14Aṣọ títa ìhà ẹnu-ọ̀nà kan jẹ́ mita mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.