Eksodu 38:13
Exodus 38:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀.
Exodus 38:13 in English
Exodus 38:13 · Berean Standard Bible
And the east side, toward the sunrise, was also fifty cubits long.
Context
11Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 12Ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀. 13Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀. 14Aṣọ títa ìhà ẹnu-ọ̀nà kan jẹ́ mita mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mita mẹ́fà ààbọ̀ pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.