Eksodu 34:5
Exodus 34:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa.
Exodus 34:5 in English
Exodus 34:5 · Berean Standard Bible
And the LORD descended in a cloud, stood with him there, and proclaimed His name, the LORD.
Context
3Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà; bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà.” 4Bẹ́ẹ̀ Mose sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sinai lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀. 5Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa. 6Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, 7Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.