Eksodu 34:4
Exodus 34:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ Mose sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sinai lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀.
Exodus 34:4 in English
Exodus 34:4 · Berean Standard Bible
So Moses chiseled out two stone tablets like the originals. He rose early in the morning, and taking the two stone tablets in his hands, he went up Mount Sinai as the LORD had commanded him.
Context
2Múra ní òwúrọ̀, kí o sì wá sórí òkè Sinai. Kí o fi ara rẹ hàn mí lórí òkè náà. 3Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà; bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà.” 4Bẹ́ẹ̀ Mose sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sinai lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀. 5Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa. 6Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.