Native Bible

Exodus 34:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣe ohun tí Èmi pàṣẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde níwájú rẹ.

Exodus 34:11 in English

Exodus 34:11 · Berean Standard Bible

Observe what I command you this day. I will drive out before you the Amorites, Canaanites, Hittites, Perizzites, Hivites, and Jebusites.

Context

9Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.” 10Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ Èmi yóò ṣe ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀-èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrín wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí Èmi Olúwa yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó. 11Ṣe ohun tí Èmi pàṣẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde níwájú rẹ. 12Máa ṣọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ̀ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdẹwò láàrín rẹ. 13Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Aṣerah wọn. (Ère òrìṣà wọn.)

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.