Native Bible

Exodus 34:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Aṣerah wọn. (Ère òrìṣà wọn.)

Exodus 34:13 in English

Exodus 34:13 · Berean Standard Bible

Rather, you must tear down their altars, smash their sacred stones, and chop down their Asherah poles.

Context

11Ṣe ohun tí Èmi pàṣẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde níwájú rẹ. 12Máa ṣọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ̀ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdẹwò láàrín rẹ. 13Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Aṣerah wọn. (Ère òrìṣà wọn.) 14Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn, nítorí Olúwa, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Òjòwú, Ọlọ́run owú ni. 15“Máa ṣọ́ra kí ẹ má ṣe bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, tí wọ́n sì rú ẹbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.