Native Bible

Exodus 33:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè, nítorí inú mi dún sí o, Èmi sì mọ̀ ọ́n nípa orúkọ rẹ̀.”

Exodus 33:17 in English

Exodus 33:17 · Berean Standard Bible

So the LORD said to Moses, “I will do this very thing you have asked, for you have found favor in My sight, and I know you by name.”

Context

15Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ. 16Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?” 17Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè, nítorí inú mi dún sí o, Èmi sì mọ̀ ọ́n nípa orúkọ rẹ̀.” 18Mose sì wí pé, “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.” 19Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí Èmi yóò ṣàánú fún, Èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí Èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.