Eksodu 33:15
Exodus 33:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ.
Exodus 33:15 in English
Exodus 33:15 · Berean Standard Bible
“If Your Presence does not go with us,” Moses replied, “do not lead us up from here.
Context
13Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́n, kí n sì le máa wá ojúrere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀-èdè yìí ènìyàn rẹ ni.” 14Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.” 15Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ. 16Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?” 17Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè, nítorí inú mi dún sí o, Èmi sì mọ̀ ọ́n nípa orúkọ rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.