Native Bible

Exodus 30:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mita ní gígùn, ìdajì mita ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

Exodus 30:2 in English

Exodus 30:2 · Berean Standard Bible

It is to be square, a cubit long, a cubit wide, and two cubits high.* Its horns must be of one piece.

Context

1“Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kasia kan; máa jó tùràrí lórí rẹ̀. 2Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mita ní gígùn, ìdajì mita ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. 3Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì ṣe wúrà gbà á yíká. 4Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní òdìkejì ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fi gbé e.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.