Native Bible

Exodus 29:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ìwọ yóò sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n

Exodus 29:8 in English

Exodus 29:8 · Berean Standard Bible

Present his sons as well and clothe them with tunics.

Context

6Ìwọ yóò sì fi fìlà dé e ní orí, ìwọ yóò sì ṣe adé mímọ́ sára fìlà náà. 7Nígbà náà ni ìwọ yóò sì mú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì yà á sí mímọ́ nípa dída òróró sí i ní orí. 8Ìwọ yóò sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ìwọ yóò sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n 9ìwọ yóò sì fi fìlà dé wọn ni orí. Nígbà náà fi ọ̀já àmùrè di Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Iṣẹ́ àlùfáà yóò máa jẹ́ tiwọn ní ìlànà títí ayé. “Báyìí ni ìwọ yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́. 10“Ìwọ yóò sì mú akọ màlúù wá síwájú àgọ́ àjọ, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé akọ màlúù ní orí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.