Native Bible

Exodus 29:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́.

Exodus 29:36 in English

Exodus 29:36 · Berean Standard Bible

Sacrifice a bull as a sin offering each day for atonement. Purify the altar by making atonement for it, and anoint it to consecrate it.

Context

34Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn. A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni. 35“Báyìí ni ìwọ yóò ṣì ṣe fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ohun gbogbo ti mo paláṣẹ fún ọ, ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi yà wọ́n sí mímọ́. 36Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́. 37Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́. Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ mímọ́. 38“Èyí ni ìwọ yóò máa fi rú ẹbọ ní orí pẹpẹ náà: Ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.